Ààbò
A gba ààbò iṣẹ́ àkànṣe WordPress àti ecosystem rẹ̀ ní pàtàkì. Pẹ̀lú ìtàn tó ju ọdún 20 lọ àti fífún ju 43% web lágbára, a pinnu láti rí i dájú pé ààbò wà fún gbogbo ènìyàn, láti àwọn blogger tó ń dá ṣiṣẹ́ dé àwọn enterprise organization.
WordPress gba ìṣípayá onídùúró níyànjú fún àwọn àìpé nínú àárín WordPress, nínú àwọn plugin àti theme tó wà lórí WordPress.org, tàbí nínú àyíká WordPress gbogbogbòò.
Tí o bá gbàgbọ́ pé o ti rí àìpé kan nínú WordPress, jọ̀wọ́ pa á mọ́ sí àṣírí kí o sì sọ fún Ẹgbẹ́ Ààbò WordPress.
Tí o bá gbàgbọ́ pé o ti rí àìpé kan nínú plugin tàbí theme WordPress tó wà lórí WordPress.org, jọ̀wọ́ pa á mọ́ sí àṣírí.
- For plugin vulnerabilities, report it to the plugin developer and the plugins team.
- Fún àwọn àìpé ààbò theme, sọ fún theme developer àti ẹgbẹ́ àtúnyẹwò theme.
Ọ̀nà tí a ń gbà ṣiṣẹ́
Iṣẹ́ àkànṣe WordPress ti pinnu láti pèsè pẹpẹ tó dúró ṣinṣin, tó ní ààbò, tó sì gbẹ́kẹ̀lé fún ohun tó ju 43% ti web lọ. Ìgbésẹ̀ ìdàgbàsókè core WordPress ní àyẹ̀wò code ní gbogbo ìgbésẹ̀, pẹ̀lú àwọn ìkópa orísun ṣíṣí tí àwọn committer tó gbẹ́kẹ̀lé ń ṣàyẹ̀wò.
Ẹgbẹ́ Ààbò WordPress ń ṣiṣẹ́ láti ṣàwárí àti láti yanjú àwọn ọ̀ràn ààbò kaakiri core WordPress, láti mú ètò ìṣiṣẹ́ náà le koko lòdì sí àwọn ewu bíi OWASP Top Ten, àti láti pèsè ìtọ́sọ́nà kaakiri àyíká.
Ní àfikún sí àwọn ògbógi tó gbẹ́kẹ̀lé ju 50 lọ, pẹ̀lú àwọn lead developer, àwọn oníwáàdí ààbò, àti àwọn olùkópa pàtàkì sí gbogbo apá WordPress, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Ẹgbẹ́ Ààbò tí a ń ṣètìlẹ́yìn fún (sponsored) ya àkókò sọ́tọ̀ láti ṣàwárí àti láti yanjú àwọn àníyàn nínú ètò ìṣiṣẹ́ àti àyíká.
Láti yanjú àwọn àìpé ààbò tí a ṣípayá lọ́nà onídùúró, Ẹgbẹ́ Ààbò ń ṣiṣẹ́ láti ṣe àwọn àtúnṣe, ṣẹ̀dá àwọn ìdánwò tó lágbára, àti láti ṣe àtẹ̀jáde àwọn àtúnṣe wọ̀nyẹn nínú àwọn ẹ̀dà bugfix. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yà tuntun WordPress nìkan ni a ṣe ìtìlẹ́yìn fún lọ́fíìsì, Ẹgbẹ́ Ààbò tún ṣe àtúnṣe fún àwọn ẹ̀yà àtijọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ̀, láti rí i dájú pé àwọn ìkànnì àtijọ́ gba àwọn àtúnṣe ààbò pàtàkì nípasẹ̀ auto-updates.
Ẹgbẹ́ Ààbò tún ń ṣiṣẹ́ tààrà pẹ̀lú àwọn olùgbàlejò ìkànnì ńlá àti àwọn olùpèsè ààbò láti ṣàwárí àti dín àwọn ewu tó ń halẹ̀ mọ́ àwọn ìkànnì WordPress kù, pẹ̀lú ṣíṣàkóso ẹ̀dà àti ìdàgbàsókè àwọn ìdènà web application firewall (WAF).
Kọ́ síwájú sí i nípa ìdúró ààbò iṣẹ́ àkànṣe WordPress nínú whitepaper wa.
Àwọn Plugin Developer
Ìtọ́sọ́nà Ààbò nínú ìwé ìtọ́sọ́nà Common APIs ni ìtọ́sọ́nà rẹ fún àwọn ìlànà ìdàgbàsókè tó ní ààbò.
Tí o bá gbàgbọ́ pé o ti ṣàmì ìṣòro ààbò kan nínú plugin tìrẹ, ẹgbẹ́ plugin WordPress wà níbí láti ràn ọ́ lọ́wọ́.
Find out more about how to address security issues in your plugin.
Àwọn Theme Developer
Ìtọ́sọ́nà Ààbò nínú ìwé ìtọ́sọ́nà Common APIs ni ìtọ́sọ́nà rẹ fún àwọn ìlànà ìdàgbàsókè tó ní ààbò.
Tí o bá gbàgbọ́ pé o ti ṣàmì ìṣòro ààbò kan nínú theme tìrẹ, ẹgbẹ́ àtúnyẹwò theme WordPress wà níbí láti ràn ọ́ lọ́wọ́.
Wá àlàyé síwájú sí i nípa bí o ṣe lè yanjú àwọn ọ̀ràn ààbò nínú theme rẹ.
Àwọn Olùgbàlejò Ìkànnì
Ìtọ́sọ́nà Ààbò nínú ìwé ìtọ́sọ́nà Advanced Administration ní àwọn ìsọfúnni pàtàkì nípa bí o ṣe lè ṣe ààbò àyíká ìgbàlejò ìkànnì rẹ.
A tún gba ọ nímọ̀ràn gidigidi láti ṣe àtẹ̀jáde ìlànà ìṣípayá onídùúró tìrẹ.